Èèmọ̀! Ọmọ wòlíì f'orúkọ wòlíì míràn lu jìbìtì, gba ₦18m lọ́wọ́ àwọn tó ń wá ojútùú sí ìṣòro ayè wọn lórí ayélujára
Oríṣun àwòrán,Ogun State Police
Published
ìṣẹ́jú 12 sẹ́yìn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Fun ẹsun pipe ara rẹ ni ohun ti a ko jẹ, fifi orukọ olorukọ lu jibiti owo to to miliọnu mejidinlogun naira (18m), ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ẹka ti ilu Ilaro ti fọwọ ofin mu Adewale Ogoemi Arojah, ẹni ti wọn ni pasitọ ni baba rẹ, amọ to n fi orukọ pasitọ miran lu jibiti owo lori ayelujara.
DSP Oluseyi Babaseyi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fi atẹjade to kede iṣẹlẹ yii sita l'Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii.
Alukoro sọ pe oju opo Facebook ni Arojah ti n purọ fawọn eeyan to ni iṣoro kan tabi meji, to n pe ara rẹ ni Pasitọ Muyiwa Akogun ti iyẹn jẹ wolii to gbajumọ, to si lo orukọ rẹ fi gba miliọnu mejidinlogun naira.
Skip content and continue reading- "Àwa òbí ni a dá owó dọ́là fáwọn ajínigbé kí wọ́n tó tú àwọn àgùnbánirọ̀ ọmọ wa sílẹ̀, ọmọ mi kò sìnrúùlú mọ́ ní Imo"8 Ọ̀wàrà 2026
- Awọn òṣèré ayé òde òní ò láàánú mọ́, t'ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀ - Murphy Ray Eyiwumi8 Ọ̀wàrà 2026
End of content
Bawo ni aṣiri sẹ tu?
Gẹgẹ bi DSP Babaseyi ṣe ṣalaye, Muyiwa Akogun tawọn eeyan mọ si "Prophet Dr. Muyiwa Akogun," lori Facebook, lo mu ẹjọ lọ si tẹsan lọjọ kẹta oṣu Kẹwaa yii.
Pasitọ Akogun ṣalaye fawọn ọlọpaa, pe awọn eeyan ti n sọrọ lori owo nla ti ẹnikan n gba lọwọ wọn lorukọ Muyiwa Akogun.
O ni ẹni naa ṣi oju opo Facebook ayederu, o si pe orukọ rẹ ni Muyiwa Akogun, bẹẹ lo n fi orukọ naa gbowo lọwọ awọn eeyan pẹlu ẹtan, to n sọ fun wọn pe oun yoo ba wọn gbadura, oun yoo ba wọn ṣẹgun aye wọn.
Eyi ni awọn ọlọpaa ilu Ilaro ṣiṣẹ tọ, wọn si bẹrẹ si I wa bi wọn yoo ṣe mu ayederu Muyiwa Akogun naa.
Abule kan nitosi Ajegunle, lagbegbe Ilaro/ Ibogun ni wọn ti pada ri i mu bi DSP Babaseyi ṣe ṣalaye.
Skip Èyítí A Ń Kà Jùlọ and continue readingÈyítí A Ń Kà Jùlọ- Mọ̀ nípa òfin ìṣàkóso gáréèjì ọkọ̀ èrò tí Adeleke buwọ́lù l'Osun lẹ́yìn rògbòdìyàn ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò
- Ṣé lóòótọ́ ni bàlúù ọmogun Naijiria míì fi pàjáwìrì bà sínú oko kan, lẹ́yìn èyí tó pa èèyàn 25 ní Igbokoda? Àlàyé rèé
- Èmi ò mọ̀ bóyá wọ́n sanwó ìtúsílẹ̀ kankan lórí àwọn àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé n'Imo- Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Imo
- Àlàyé lórí bí ìbejì ọmọ ìyá kan náà ṣe kú láàárín ọjọ́ méjì síra wọn, ohun gangan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn
End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ
Skip content and continue reading- 'A kò tíì ri ara bàlúù náà gan, awakọ̀ bàlúú yìí ni ì bá lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó - Gómìnà Lucky Aiyedatiwa8 Ọ̀wàrà 2026
- Àlàyé lórí bí ìbejì ọmọ ìyá kan náà ṣe kú láàárín ọjọ́ méjì síra wọn, ohun gangan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn8 Ọ̀wàrà 2026
End of content
Afurasi jẹwọ
Atẹjade ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe lasiko tawọn agbofinro n fi ọrọ wa Arojah Ogoemi tọwọ ba lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ loun n lo orukọ Pasitọ Akogun loju opo Facebook.
Wọn ni Arojah jẹwọ pe oun n lo orukọ Pasitọ Akogun lati jiṣẹ èké ati asọtẹlẹ irọ.
O ni oun n lo orukọ naa fi ṣeto adura fawọn eeyan to ni iṣoro, nipasẹ eyi lo ni oun fi n gbowo lọwọ wọn nilẹ yii ati loke okun.
Iwadii ọlọpaa fi han, pe Arojah maa n dọdẹ awọn to n bẹbẹ adura loju opo Pasitọ Muyiwa Akogun, yoo bẹrẹ si I ba wọn sọrọ, nibẹ lo si gba wọle si ọpọlọpọ wọn lara lori ayelujara to si gba 18m lori irọ.
Ṣaa, wọn ti taari rẹ si ẹka to n wadii iwa ọdaran, eyi to wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Eleweeran l'Abeokuta.